Oríṣun àwòrán, @Kunle Ologundudu
Gbajugbaja akewi sọ̀rọ̀ sawon asebajẹ lawujọ paapaa awọn Oloselu ni, Kunle Ologundudu ti ni iku ko si loju oun bayii.
O ni asiko onikaluku yatọ ati pe asiko ti oun ko tii to rara.
Awọn ọmọ Naijiria ti n bẹnu atẹ lu awọn to gbe iroyin ẹlẹjẹ pe gbajugbaja akewi ilẹ Yoruba, Kunle Ologundudu ti kagbako iku lọwọ awọn agbebọn.
Kunle Ologundudu gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ padanu ẹmi rẹ lọwọ awọn agbebọn niwaju ile rẹ nilu Eko.
Ẹni to kọkọ ke gbajare lori iroyin ofege yi ni ẹni ti ọrọ naa kan-Kunle Ologundudu.
Ọ̀rọ̀ Baba Ijesha tí graph dá sí ló mú kí àwọn tó ń bá a jà ro ikú sí mi- Ologundudu
Kí ló pa Ologundudu àti Baba Ijesha pọ̀ débi pé ìròyìn ikú rẹ̀ gborí ayélujára?
Ninu fọnran fidio kan, o ṣalaye pe ṣadede loun bẹrẹ si ni gba ipe lorisirisi tawọn eeyan si fẹ mọ mode boya lootọ lo kagbako iku.
O ṣalaye pe ọrọ naa ko ṣẹyin bi oun ti ṣe dasi ọrọ awuyewuye ballot vote niṣe pẹlu oṣere tiata Yoruba Olanrewaju James taa mọ si Baba Ijesha.
'' Nkan to ṣẹlẹ ni pe ọrọ baba Ijesha ti mo da si lo jẹ ki awọn to n ba ja fẹ maa gbe 'rumours' kiri nipa mi''
Oríṣun àwòrán, Facebook Screenshot/Femi Salako
O ni idi ti wọn fi n ṣe bẹ ni ki irẹwẹsi ọkan le de ba oun lati le ma ja fun ifi idajọ ododo lelẹ.
Ologundudu sọ pe awọn to gbe iroyin yi kaakiri lero wi sort Eko loun wa ṣugbọn oun ko si ni Eko rara.
Ologundudu ni: ''O yẹ ki a yọju sile ẹjọ lori ọrọ Baba Ijesha ṣugbọn mi o raye. Ife ni mo wa.
O ni koda, Ife ni mo wa titi di bi a ṣe n sọrọ yi''
Ninu awọn to kọ ọrọ tako iroyin yi ni Babafemi Ojudu to jẹ oludamọran pataki si aarẹ Buhari lori ọrọ oṣelu.
Ojudu bẹnu atẹ lu iwa yi to si ni iru iṣẹ iroyin kikọ bayi ko bojumu rara.
''Mo ji lowurọ oni lati ka nipa iroyin kan pe Kunle Ologundudu ti ti maa fi kan si, o ni kokoko lara oun le ati pe lati ago meji oru lawọn eeyan ti n pe oun lori ago''.
Ojudu sọ pe awọn akọroyin ti ko kọṣẹ iroyin yi ti n da wahala sil plu agbelẹkọ iroyin wọn.
Ojudu ṣapejuwe wọn gẹgẹ bi alaburu ẹda ti wn fẹ maa da wahala silẹ lawujọ.
Lakotan, o sọ pe pẹlu nkan to n ṣẹlẹ yi, oun ti wa gba wi pe o yẹ ki wọn fofin de iroyin ayelujara.
''O yẹ ki wọn ṣagbekal ilana bibẹẹkọ, iroyin ayederu le dana sun orileede wa''